Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu

Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu

Bí ayé ni mo wà nígbà tí wọ́n yọ Olumo Rock ní inú mi, bí ọ̀run ní mí ò mọ̀- Olaiya Igwe

Agbaọjẹ osere Yoruba ti ọpọ n pe ni Olaiya Igwe gbalejo BBC Yoruba lẹyin ti ori kọ o yọ ninu idubulẹ aisan rẹ.

Ebun Oloyede to fi Abeokuta ṣe ibujoko rẹ ṣalaye pe oun ko le sọ boya ye lo ran aisan naa si oun ni tabi amuwa Olorun ni.

Igwe Olaiya

Oríṣun àwòrán, others

O ni oun ti oun mọ ni pe oun dupẹ pe aisan kindinrin naa ko mu ẹmi oun lọ nitori pe oun ri aanu Olorun gba.

Olaiya Igwe sọ pataki omi mimu ninu agọ ara ẹda nitori pe omi ti oun mu lo tun aye oun ṣe nigbẹyin.

Olaiya Igwe ni ẹni to kede iku oun ro pe UCH ni oun wa ni ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ.

O ni koda, oun ko mọ boya aye ni oun wa tabi ọrun lasiko idojukọ naa ṣugbọn oun dupe pe ko mu ẹmi oun lọ.

Olaiya Igwe fi imoore rẹ han si Adẹdaa ati gbogbo awọn ololufẹ rẹ pe Oba Oke da ẹmi rẹ pada.