Anthony Joshua kékeré: Mo fẹ́ kí ẹ̀ṣẹ́ gbé mi lọ sí òkè okun - Tijani Azeez

Anthony Joshua kékeré: Mo fẹ́ kí ẹ̀ṣẹ́ gbé mi lọ sí òkè okun - Tijani Azeez

Ọmọ ọdun mẹrinla abẹṣẹkubiojo ni Tijani Azeez to si jẹ akẹkọọ ni ile iwe ati ni ile ẹk to ti n kọ ẹṣẹ jija.

"Ti mo ba lọ ileewe laarọ, ti mo de ni ago mẹrin, maa tun bẹrẹ si ni kọ ẹkọ ẹṣẹ di ago meje alẹ".

Tijani Azeez

Lati ọmọ ọdun meji ni ọmọ ọdun mẹrinla yii ni oun ti bẹrẹ ẹṣẹ jija toripe baba rẹ gan lo si ọna yii.

Tijani Azeez àti bàbá ẹ̀

Gbogbo igba ni inu Tijani maa n dun si ohun to fẹran lati maa ṣe yii to bẹẹ to jẹ wipe iye ọjọ ati wakati to fi n kọ ẹṣẹ jija laarin ọsẹ kan ko lonka rara.

Olukọni to n kọ tijani bo ṣe n ja ẹṣẹ jẹ onimọ to ti n kọ ẹṣẹ lati ọdun 2003 koda o wu oun gan ki ọmọ to bi funrarẹ maa ja ẹṣẹ.

Ọpọlọpọ ọrọ iwuri lo sọ nipa Tijani azeez.