Dare Adeboye news: Ìdílé Pásítọ̀ Dare, ọmọ́ Pásítọ̀ Adeboye fẹ́ dá wà lásìkò yìí

Pasito Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, thehgservice

Ijọ Irapada iyẹn Redeem Christian Church of God ti kede pe kii ṣe Covid-19 to wa lode lo mu ẹmi Pasitọ Dare Adeboye, ọmọ oludari ijọ naa lọ.

Ninu atẹjade ti ẹka ijọ naa to nmojuto eto ipagọ adura oloṣooṣu, "the holyghost service" fi sita ni aridaju yii ti wa.

Atẹjade ọhun sọ imọlara ẹbi ati ijọ RCCG nipa iṣẹlẹ yii, igbe aye rere oloogbe ati imulọkanle wipe awọn ati Dare Adeboye yoo pade lẹsẹ Jesu Kristi lọrun nibi ti ko si inira mọ.

Pasito Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, psfrccgofficial

Atẹ̀ade naa tun tọrọ̀ gafara lọwọ awọn eeyan lati da wa lasiko idaro ti wọn wa.

"O wu mọlẹbi lati da wa lasiko yii a si gbadura pe Ọlrun yoo wa pẹlu yin bi ẹ ṣe gbọ ibeere ẹbẹ wa yii".

Àkọlé fídíò, 'Ẹ kálọ sí ìlú mi'... Ètò ńlá tó bẹ̀ sílẹ̀ kìjà lórí BBC Yorùbá
Atẹjade

Oríṣun àwòrán, thehgservice

Lopin atẹjade naa ni wn kọ gadagba pe " a fẹ ki gbogbo eeyan mọ wipe iku yii ko ni nkankan ẹ pẹlu aisan Covid-19 rara".

Apapọ ẹgbẹ awọn ọmọ Pasitọ ni ijọ Redeemed Christian Church of God ti fi ikede sita ọjọ ti Oluwadamilare Temitayo Adeboye jade laye amọ ti ko tete han fun gbogbo eeyan.

Loju opo Twitter wọn ni wọn ti fi atẹjade sita to sọ pe "pẹlu ọkan wuwo la fi kede ipapoda ọmọ wa, ẹgbọn wa, ọkọ ati baba wa, Oluwadamilare Temitayo Adeboye to lọ ba Ọlọrun ni ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrin oṣu karun ọdun 2021".

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

End of Instagram post, 1

Atẹjade naa ka wipe igbe aye rẹ jẹ igbe aye rere gẹgẹ bo ṣe sin Ọlọrun lai kaarẹ, to n fun ni tp si n dari lai si ifoya.

"Bo tilẹ jẹ pe iroyin yii fi wa gidi gan, a duro lori Jesu Kristi ninu ẹni ti a ni idaniloju pe a o pade nibi ti ko si inira".

Skip Twitter post, 1
Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

End of Twitter post, 1

Leke Ati Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, Pastor Dee

Ọ̀rọ̀ Leke Adeboye, aburo oloogbe

"A mú olódodo lọ́ ṣáájú ọjọ́ ibi..."

Ni owurọ kutukutu oni ni abigbẹyin oludari ijọ RCCG, Pasitọ Leke Adeboye fi ọrọ sita lati inu iwe owe inu bibeli eyi to lọ mọ iroyin to n jade lori ayelujara pe ẹgbọn rẹ, Pasitọ Dare Adeboye ti jade laye.

Ọpọlọpọ ero lo ti n wọ loju opo Facebook Leke lori ọrọ to fi sita yii ti wọn si ti n ba idile Adeboye ati ijọ RCCG kẹdun.

Pasitọ Leke ati Dare Adeboye jọ jẹ ọmọ gbajugbaja Pasitọ ati oludari ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye.

Leke Adeboye to tun jẹ oluranlọwọ agba fun oludasilẹ ijọnaa fi ẹsẹ bibeli, Iwe Isaiah 57:1 si oju opo rẹ eyi to sọ pe:

"Olódodo ṣègbé kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀;

a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ, kò sì ṣí ẹni tó yé pé

a ti mú àwọn olódodo lọ láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi".

Aworan oju opo Leke Adeboye

Oríṣun àwòrán, Leke Adeboye

Bo tilẹ jẹ pe ko tii si mọlẹbi kankan to jade wa fi orukọ oloogbe naa sita lori ohun to ṣẹlẹ, kẹtikẹti lero n wọ lati ba Pasitọ Leke Adeboye kẹdun lori ayelujara.

Ibanikẹdun iku Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, Leke Adeboye

Ibanikẹdun iku Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, Leke Adeboye

Ibanikẹdun iku Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, Leke Adeboye

Iroyin naa tẹ wa lọwọ ni yajoyajo pe Pasitọ Dare Adeboye to jẹ ọmọ oludari ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Adejare Adeboye ti jade laye.

Ọkan lara awọn Pasitọ agba ijọ RCCG to tun jẹ eeyan to ṣee fọkan tan ni ijọ naa sọ fun BBC Yoruba pe lootọ ni awọn ti gbọ iroyin naa.

Pasito Dare Adeboye ati iya rẹ

Eekan miiran ti a tun kan si jẹ ko di mimọ pe oun ko fẹ ki awọn oniroyin maa gbe iroyin ti ko jẹ ootọ nipa iṣẹlẹ yii.

Amọ o fi aridaju ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba pe lootọ ni Pasitọ Dare dagbere faye.

Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, Leke Adeboye

Ẹwẹ, o ni adura ni ki gbogbo eeyan maa gba fun mọlẹbi Adeboye ki wọn ri itunu ati okun Ọlọrun.

O ni dajudaju ki ọsẹ yii to kanlẹ, mọlẹbi yoo fi ọrọ ẹbi sita nipa rẹ.

Ẹwẹ, o tẹ ẹ mọ akọroyin BBC leti wipe irọ patapata gbaa ni iroyin ti awọn kan n gbe pe aisan Covid-19 tàbí ijamba ọkọ lo ṣokunfa iku oloogbe.

"Ki gbogbo eeyan kọ eti ikun si iroyin to n sọ pe iku Covid-19 tabi ijamba ọkọ lo pa Pasitọ Dare".

Pasitọ Dare jẹ ọkan lara awọn Pasitọ agba fun ẹka ijọ awọn ọdọ RCCG ni ilu Abuja ti iroyin si sọ pe oun lo waasu ni ijọ rẹ lọjọ isinmi to kọja yii.