Baba Ijesha: Fídíò tí Iyabo Ojo gbé jádé lo ṣàfihàn Ijesha tó ń bẹ̀bẹ̀

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha

Ọrọ ẹsun ti wọn fi kan baba Ijesha ti n gba ọna miran yọ bayii nitori Iyabo Ojo, gbajumọ osere tiata kan ti gbe fidio kan jade ninu eyi ti Baba Ijesha wa.

Ninu fọnran aworan naa ni Baba Ijesha ti joko silẹ, to si n bẹbẹ pe ki wọn dari jin oun.

Fidio naa ti Iyabo Ojo gbe soju opo Instagram rẹ lo se afihan Baba Ijesha to n sọ pe ki wọn dari jin oun nitori isẹ esu ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Baba Ijesha, ti awọn eeyan kan n fi ọrọ wa lẹnu wo, to fi mọ iya ọmọ naa, lo n salaye ohun to ri lọbẹ, to fi wa iru sọwọ.

Ninu fidio naa ni iya ọmọ, Princess ti yari, to si fẹ lu Baba Ijesha amọ ti awọn eeyan n bẹ lati mase se bẹẹ.

Baba Ijesha, ninu fidio naa lo salaye pe oun ni ogun idile, eyi to han si Princess funra rẹ, ti isẹlẹ naa ko si le se ẹyin ogun to n ja oun.

"Lootọ ni mo se ohun ti ko dara, ẹ jọọ, ẹ dari jin mi tori Ọlọrun, mo mọ pe mo sẹ, mo se nnkan ti ko dara, ma wo temi, jọọ mo bẹbẹ ni.

Oju ko ni tiẹ, jọọ, ko yẹ ki n se eleyi si ọ, n ko mọ ohun to se mi, mo si le pa ara mi."

Nigba ti Princess, iya ọmọ n bi Baba Ijesha pe ki lo de to se wa nawọ̀ ere si ọmọ ọdun meje, to tun pada wa se bẹẹ ni igba keji, baba Ijesha ko ri ohunkohun sọ, o sa kan n bẹbẹ ni.

Lẹyin o rẹyin ni wọn wa mu Baba Ijesha lọ si agọ ọlọpaa lori ẹsun naa.

Amọ nitori pe ẹjọ naa ti de ile ẹjọ, to si ti di ọrọ ofin, ileesẹ BBC ko le se afihan fọnran aworan naa loju opo wa.