Kwara Hijab Crisis: Ẹ ṣe ohun tí àwọn Kristẹni Ilorin ń fẹ́ tàbí kí ẹ kó àwọn ọmọ yín kúrò nílé ẹ̀kọ́ wọn - Oyedepo

Oyedepo

Oríṣun àwòrán, @DavidOyedepoMin

Oludasilẹ ijọ Living Faith ti ọpọ mọ si Winners, ti ke si awọn Musulumi niluu Ilorin lati ko awọn ọmọ wọn lọ sile ẹkọ awọn Musulumi ti wọn ba fẹ ki wọn maa lo ijaabu.

Oyedepo lo sọ ọrọ naa ninu iwaasu kan to ṣe lẹyin rogbodiyan ọrọ ijaabu to waye nile ẹkọ Baptist ati ECWA ni Ilorin.

Ṣaaju ni Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq, ti kọkọ paṣẹ pe awọn akẹkọọ to jẹ Musulumi le maa wọ ijaabu nile ẹkọ ti awọn ọmọlẹyin Kristi da silẹ.

Ṣugbọn aṣẹ naa ko dun mọ awọn Kristẹni ilu Ilorin ninu, eyii to da rogbodiyan silẹ.

Oyedepo ni "ohun to n ṣẹlẹ ni Kwara jẹ eyii to ba ni ninu jẹ gidi, nibi ti awọn awọn Musulumi ti sọ fun awọn Kristẹni lati gba ijaabu laaye nile ẹkọ ti wọn da silẹ"

"Mi o tii ri ibikibi laye yii ti ayalegbe yoo ti maa paṣẹ fun onile... eredi rẹ si ni pe a ko tii fi odikeji Ọlọrun han wọn."

Àkọlé fídíò, Bí Oduduwa Republic bá bẹ̀rẹ̀, a ò ní ṣe aburú fún àwọn tó takò wá, ìlànà ààtẹ̀lé rèé - Banji Akintoye

Alufaa naa sọ pe o yẹ ki wọn kilọ fun awọn ẹlẹsin miran pe ki wọn ṣọra fun awọn Kristẹni, ki wọn ma baa ri ibinu Ọlọrun.

Oyedepo pari ọrọ rẹ pe ki awọn Musulumi ti ohun ti awọn Kristẹni n fẹ ko ba tẹ lọrun ko awọn ọmọ wọn lọ sile ẹkọ to jẹ ti awọn Musulumi.

"Ẹ dẹkun ati maa ki ika si oju ẹlomiran nigba ti wọn kii ṣe afọju," Oyedepo lo kilọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, 'Pẹ̀lú gbogbo ìrìnàjò Dubai mi, ẹ̀sẹ̀ gígún ní Nàìjíríà láti pàdé èèyàn ńlá ńlá tó lè ra àwòrán wa ṣe pàtàkì'

Ẹnikẹ́ni tó bá fa wàhálà míì lẹ́yìn rògbòdìyàn ọ̀rọ̀ Hijab tó wáyé n'Ilorin yóò fojú winá òfin - AbdulRazaq

Ilorin

Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ẹnikẹni to ba fa wahala nitori rogbodiyan ọrọ ijaabu to waye niluu Ilorin yoo foju wina ofin.

AbdulRazaq lo sọ ọrọ naa lasiko to n ba awọn eeyan ipinlẹ naa sọrọ lọjọ Isẹgun lẹyin rogbodiyan to waye ṣaju nile ẹkọ Batist ati ECWA niluu Ilorin.

Wahala ọhun bẹ silẹ lẹyin ti gomina ọhun kede lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii pe, awọn akẹkọbinrin to jẹ Musulumi le maa wọ ijaabu lọ sile ẹkọ ti awọn Kristẹni da silẹ.

Igbesẹ naa ko dun mọ wọn adari ile ẹkọ Kristẹni ọhun ninu, eyii to da wahala silẹ.

O ni oun ti kọkọ ṣe ipade pẹlu awọn ti ọrọ naa kan ṣaaju ki oun to gbe igbẹsẹ ọhun.

AbdulRazaq tun sọ pe gẹgẹ bii gomina, oun ti bura lati daabo bo awọn eeyan ilu lọwọ wahala ki irufẹ wahala bẹẹ to bẹ silẹ.

O fikun pe oun yoo ṣe atunsẹ si igbimọ to n ri si ọrọ naa ti oun ti gbe kalẹ ṣaaju laarin ọjọ diẹ si asiko yii, ki ọrọ naa patapata.

Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ awọn adari ẹsin Kristẹni ati Musulumi fun akitiyan wọn ki alaafia le jọba niluu Ilorin ati lọwọ awọn agbofinro naa fun ipa ti wọn sa lati pana rogbodiyan to bẹ silẹ ṣaaju.

Gomina naa pari ọrọ rẹ pe, ki awọn eeyan ipinlẹ Kwara gbiyanju lati fi imọ ṣokan fun itẹsiwaju ipinlẹ naa lai fi ti ẹya tabi ẹsin ṣe.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀rọ̀ Yorùbá kan wà tí ẹ kò lè lò pọ̀ mọ́ ara wọn, àwn ọ̀rọ̀ tẹ́ẹ lè fi rọ́pò rèé

Akẹ́kọ̀ọ́ kò yọjú sílé ẹ̀kọ́ lẹ́yìn tí àwọn olùkọ́ padà sẹnu iṣẹ́ nílèèwẹ tí rògbòdìyàn Hijab ti wáyé n'Ilorin

Ilorin

Awọn olukọ lawọn ile ẹkọ ti ijọba ti pàṣẹ iwọle pada ni ipinlẹ Kwara lori ọrọ wahala lilo Hijab ti pa aṣẹ naa mọ.

Nile ẹkọ Baptisti to wa lagbegbe Surulere ti BBC Yoruba ṣabẹwo si, a ri awọn olukọ naa ti wọn ti n pada sẹnu isẹ wọn.

Ilorin

Ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn olukọ ọhun, wọn ni awọn ko ni nnkan mii lati ṣe bi ko ṣe pe ki wọn tẹle aṣẹ ijoba to gba awọn ṣiṣe.

Àkọlé fídíò, Bed Wetting: Tolulope Joseph ní ò lé ní ogún ọdún tí òun fi tọ̀ sílé kí ìwòsàn tó dé

Wamuwamu ni awọn agbofinro wa ni ẹnu ọna abawọle ile ẹkọ Baptist naa, sugbon akẹkọọ meji pere la ri nigba ti a kan sibẹ.

Alakoso ile ẹkọ girama Baptist, arabinrin Bamikole Julianah Adedoyin ti a ba sọrọ ni awọn n reti ki awọn akẹkọ yọjú, paapaa awọn to fẹ kọ idanwo asekagba WAEC.

Ilorin

O fi kun pe oun ti gbe igbeṣe lati maa pe awọn obi awọn akọkọọ naa ki wọn ma baa padanu iforukọsilẹ idanwo WAEC ọhun.

Ko si wahala kankan nigba ti a de ibẹ sugbon awon alaṣẹ ile ẹkọ naa ni awọn eeyan kan ti ja ferese ọọfisi alakoso ile ẹkọ alakọbẹrẹ, ti wọn si ba awọn irinṣẹ kan jẹ.

Olùkọ́ tí kò bá yọjú sí kíláàsì láwọn iléẹ̀kọ́ tí ìjà tí ń wáyé rugi oyin - Ìjọba Kwara

Ile iwe

Ijọba ipinlẹ Kwara ti pasẹ pe ki awọn ileẹkọ mẹwa to jẹ ti ẹlẹsin Kristẹni ti ija ti waye lori ọrọ lilo ibori bẹrẹ to ẹkọ kikọ lọgan.

Atẹjade kan ti alaga ajọ to n mojuto eto ẹkọ girama nipinlẹ Kwara, Tescom, Mallam Bello Abubakar fisita lo pasẹ bẹẹ fawọn ọga ile ẹkọ ati olukọ to wa lawọn ile ẹkọ mẹwẹẹwa naa.

Atẹjade naa ni igbesẹ pipada si kilaasi ni yoo mu ki eto ẹkọ kikọ bẹrẹ loju ẹsẹ, kawọn akẹkọjade to n mura idanwo WAEC le joko se idanwo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bello wa dunkoko pe olukọ ti ko ba yọju sibi isẹ lawọn ile ẹkọ naa loni ọjọ Ẹti rugi oyin, ti yoo si foju wina ofin ijọba nitori awọn ko ni faaye gba iwa aibọwọ fofin.

Bakan naa ni atẹjade ọhun tun fewe ọmọ mọ awọn eeyan ti ọrọ naa kan leti lati mase tapa sofin nitori ipade alaafia laarin wọn ati ijọba yoo tẹsiwaju.

Bello ni ijọba kabamọ nipa inira ti titi ilẹkun awọn ile ẹkọ naa mu bawọn akẹkọ pẹlu afikun pe ijọba gbe igbesẹ naa nitori ipese alaafia ni.

Krìstẹ́nì 15 ló farapa nínú làásìgbò Hijab Ilorin, àwọn kan tún ṣiṣẹ́ abẹ - CAN

Kristeni to fara pa

Ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi (CAN) ni ipinlẹ Kwara ti sọ pe bii eeyan marundinlogun lo ṣeṣe lasiko rogbodiyan to waye niluu Ilorin laarin awọn Kristẹni ati Musulumi.

Akọwe ẹgbẹ naa nipinlẹ ọhun, alufaa Reuben Idowu Ibitoye, lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Rogbodiyan naa ko ṣẹyin ọrọ ti ijọba ipinlẹ naa sọ pe awọn akẹkọọbinrin to jẹ Musulumi le maa lo ijaabu lawọn ile ẹkọ ti ile ijọsin da silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ibitoye ni "awọn eeyan to ṣeṣe lọjọru ti isẹlẹ naa waye le ni marundinlogun, koda wọn ṣiṣẹ abẹ fun awọn miran ninu wọn.

Lonii ẹwẹ, wọn tun ṣakọlu si awọn miran lagbegbe ECWA, ti wọn si kan awọn eeyan naa lapa ati ni ẹsẹ."

Awọn akẹkọọ to duro siwaju ile iwe wọn

Alufaa naa fikun pe, awọn gẹgẹ bii Kristẹni ko ni ija kankan pẹlu awọn Musulumi, ijọba ipinlẹ Kwara ni awọn ba ni ọrọ.

O pari ọrọ rẹ pe o yẹ ki ijọba ṣe ododo lori ọrọ naa, ki wọn ma si ṣe ojuṣaaju ninu idajọ wọn.

Ofin Naijiria fi aye gba ẹnikọọkan lati mura nilana ẹsin rẹ - Abdulhameed

Nigba to n da si ọrọ naa, Ọjọgbọn O.Y Abdulhameed, to jẹ akọwe awọn ọmọ bibi ilu Ilorin ati ọjọgbọn ni Fasiti Ilorin sọ pe, o yẹ ki gbogbo eeyan niluu Ilorin bọwọ fun ohun ti ofin sọ.

O ni "orilẹ-ede to ni ofin ni Naijiria jẹ nitori naa o yẹ ki gbogbo awọn ti ọrọ yii kan tẹle ohun ti ofin sọ."

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "ofin Naijiria, ori ọgbọn, ẹsẹ ikẹjọ fi aye fun gbogbo ọmọ Naijiria lati darapọ mọ ẹsin to ba wu wọn, bakan naa lo tun fi aye gba wọn lati mura bi ẹsin naa ṣe fi aye gba wọn."

Ilu Ilorin

Ọjọgbọn naa sọ fun BBC Yoruba pe, eeyan le mura bi ẹsin rẹ ṣe fi aye gba ni gbogbo ibi to ba jẹ ti ijọba, ti ile ẹkọ naa jẹ ọkan lara rẹ."

Akọwe ọmọ ilu Ilorin ṣalaye siwaju si pe, lootọ awọn ile ijọsin lo da awọn ile ẹkọ naa silẹ, ṣugbọn ijọba ti gba iṣakoso awọn ile ẹkọ ọhun lọwọ awọn ile ijọsin lọdun 1974.

O ni ti to ba jẹ pe ijọba lo n ṣagbatẹru awọn ile ẹkọ naa, ijọba nikan lo ni aṣẹ lati sọ bi awọn akẹkọọ ṣe le maa mura lọ sile iwe.

Lẹyin naa lo gba awọn eeyan ilu Ilorin nimọran lati fi suuru yanju ọrọ naa, ati pe ki wọn ma gba ọrọ ẹsin laaye lati ba ibagbepọ wọn jẹ.

Àkọlé fídíò, Nigerian Drone Maker: Roqeeb Aderogba ní ìgbà mẹ́fà l‘òun kùnà láti ṣe dírónù, kó tó yege

Awa ko ri ẹnikẹni ti wọn fọ lori tabi to farapa - Ọlọpaa

BBC tun kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ajayi Okasanmi Jeffery, to sọ pe awọn ko fi panpẹ ofin mu ẹnikẹni ninu awọn to da rogbodiyan silẹ niluu Ilorin.

Bo tilẹ jẹ pe o ni lootọ ni awọn gbọ pe awọn eeyan kan farapa nitori iṣẹlẹ to waye niwaju ile ẹkọ Baptist to wa ni Surulere, ṣugbọn awọn ko le fidi rẹ mulẹ pe ẹnikẹni farapa.

O sọ pe "a gbọ pe wọn fọ awọn kan lori, ṣugbọn awa ko ri ẹnikẹni ti wọn fọ lori tabi to farapa."

Jeffery pari ọrọ rẹ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati pana rogbodiyan to n waye niluu Ilorin nitori ọrọ ijaabu ọhun.

Ilorin dàrú lórí àṣẹ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Musulumi má a lo ìbòrí nílé ẹ̀kọ́ Krìsìtẹ́nì

Musulumi ati kristieni n sọ oko sira wọn niwaju ile ijọsin

Ọrọ ti di boolọ o yago fun mi ni ilu Ilọrin laarin awọn Musulumi ati Kristiẹni.

Rogbodiyan naa ko ṣẹyin ọrọ lilo ijaabu fun awọn akẹkọọbinrin to jẹ Musulumi, to n kawe nile ẹkọ ti awọn Kristẹni kọ.

Aarọ Ọjọru ni awọn Kristẹni bẹrẹ ifẹhonuhan lodi si igbeṣẹ ijọba ipinlẹ ọhun, eyi to faaye gba awọn akẹkọọbirin Musulumi lati maa lo ijaabu nile ẹkọ awọn Kristẹni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbesẹ naa ko dun mọ awọn alaṣẹ ile ẹkọ Kristẹni naa ninu, lẹyin ti wọn ti kọkọ sọ ṣaaju pe akẹkọọ yowu to ba fẹ maa kawe nile iwe awọn ko gbọdọ wọ ijaabu.

Lowurọ Ọjọru ni awọn ẹlẹsin mejeeji peju siwaju ileewe Baptist Secondary School to wa ni Suurulere, pẹlu iwe ilewọ to ni oriṣiriṣi akọle.

Ilorin

Ka to diju ki a to laa, ija ti bẹrẹ laarin awọn ẹlẹsin mejeji ọhun, ti ọlọpaa si yin afẹfẹ tajutaju soke lati tu wọn ka.

Awọn Musulumi ati Kristẹni bẹrẹ si n sọ oko sira wọn, eyii to mu awọn agbofinro yin gaasi tajutaju lọna ati pana rogbodiyan ọhun.

Titi di asiko ti a n kọ iroyin yii, awọn kristeni ti sa wọ inu ọgba sọọsi onitẹbọmi kan ni Suurulere, ti awọn Musulumi ṣi wa nita nibẹ.

Àkọlé fídíò, Farmers Herders Crisis: Rẹ́rẹ́ rún, ẹ̀mí àti dúkìá ṣòfò lágbègbè Ariwa Yewa

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun ni ijọba ipinlẹ Kwara kede ṣiṣi awọn ile ẹkọ mẹwaa kan ti ọrọ naa kan pada, eyi ti wọn gbe ti pa ṣaaju.